Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.” Aaroni dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Aaroni. Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.” Nígbà ti Aaroni rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí OLúWA.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.
Kà Eksodu 32
Feti si Eksodu 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eksodu 32:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò