Eksodu 23:20-33

Eksodu 23:20-33 YCB

“Kíyèsi èmi rán angẹli kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún. Fi ara balẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìṣedéédéé yín jì yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀. Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì ṣe ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòro àwọn tí ń fóòro yín. Angẹli mi yóò lọ níwájú rẹ, yóò sì mú ọ dé ọ̀dọ̀ àwọn ará: Amori, Hiti, Peresi, Kenaani, Hifi àti Jebusi, èmi a sì gé wọn kúrò. Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú. Ẹ̀yin yóò sí máa sin OLúWA Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ. Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn. “Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ. Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hifi, Kenaani àti Hiti kúrò ni ọ̀nà rẹ. Ṣùgbọ́n, Èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan ṣoṣo, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀jù fún ọ. Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò máa lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi pọ̀ tó láti gba gbogbo ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìní. “Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun pupa títí dé Òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate: Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ dá májẹ̀mú kankan pẹ̀lú wọn tàbí pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn gbé ni ilẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò mú ọ dẹ́ṣẹ̀ sí mi: nítorí bí ìwọ bá sin òrìṣà wọn, èyí yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fun ọ nítòótọ́.”