Àsìkò wà fún ohun gbogbo, àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run. Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu. Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́. Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù, Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀ Ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.
Kà Oniwaasu 3
Feti si Oniwaasu 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Oniwaasu 3:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò