Oniwaasu 3:1-17

Oniwaasu 3:1-17 YCB

Àsìkò wà fún ohun gbogbo, àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run. Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu. Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́. Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù, Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀ Ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà. Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀? Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn. Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láààyè. Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́. Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni. Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀, ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀. Mo sì tún rí ohun mìíràn ní abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́, òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀. Mo wí nínú ọkàn mi, “Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ènìyàn búburú, nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́, àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.”