Nígbà tí OLúWA ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin OLúWA Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀. Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA. Mo ti wólẹ̀ níwájú OLúWA fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé OLúWA sọ pé Òun yóò pa yín run. Mo gbàdúrà sí OLúWA wí pé, “OLúWA Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti rà padà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Ejibiti wá. Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, ‘Torí pé OLúWA kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní aginjù.’ Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ ni wọ́n, ogún rẹ tí o ti fi ọwọ́ agbára rẹ àti nínà ọwọ́ rẹ mú jáde.”
Kà Deuteronomi 9
Feti si Deuteronomi 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deuteronomi 9:23-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò