Deuteronomi 8:1-10

Deuteronomi 8:1-10 YCB

Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí OLúWA fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. Ẹ rántí bí OLúWA Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín ṣọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí yín ba àti láti dán an yín wò kí ó ba à le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu OLúWA wá. Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà. Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín. Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin OLúWA Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí pé OLúWA Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin. Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá. Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin OLúWA Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín.