Deuteronomi 31:1-8

Deuteronomi 31:1-8 YCB

Nígbà náà ni Mose jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Israẹli pé: “Mo jẹ́ ọmọ ọgọ́fà ọdún báyìí àti pé èmi kò ni lè darí i yín mọ́. OLúWA ti sọ fún mi pé, ‘Ìwọ kò ní kọjá Jordani.’ OLúWA Ọlọ́run rẹ fúnrarẹ̀ ni yóò rékọjá fún ọ. Yóò pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run níwájú rẹ, ìwọ yóò sì mú ìní ilẹ̀ wọn, Joṣua náà yóò rékọjá fún ọ, bí OLúWA ti sọ. OLúWA yóò sì ṣe fún wọn ohun tí ó ti ṣe sí Sihoni àti sí Ogu ọba Amori, tí ó parun pẹ̀lú ilẹ̀ ẹ wọn. OLúWA yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún ọ. Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí OLúWA Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ; Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” Nígbà náà ni Mose pe Joṣua ó sì wí fún un níwájú gbogbo Israẹli pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí OLúWA búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrín wọn bí ogún wọn. OLúWA fúnrarẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”