Deuteronomi 26:1-12

Deuteronomi 26:1-12 YCB

Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí OLúWA Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀, mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí OLúWA Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún OLúWA Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí OLúWA búra fún àwọn baba wa.” Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLúWA Ọlọ́run rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú OLúWA Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe. Nígbà náà ni a kégbe pe OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wa, OLúWA sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa. Nígbà náà ni OLúWA mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu. Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ OLúWA ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú OLúWA Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí OLúWA ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ. Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó.