Deuteronomi 10:12-21

Deuteronomi 10:12-21 YCB

Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin OLúWA Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà OLúWA tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé OLúWA Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. Síbẹ̀ OLúWA sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní. Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ. Torí pé OLúWA Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn. Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti. Ẹ bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀. Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí.