Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodikea àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí. Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀. Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìṣúra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí. Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma ba à fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín ṣìnà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsi ètò yín àti bí ìdúró ṣinṣin yín nínú Kristi ti rí.
Kà Kolose 2
Feti si Kolose 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Kolose 2:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò