Ìṣe àwọn Aposteli 8:26-38

Ìṣe àwọn Aposteli 8:26-38 YCB

Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.” Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn, Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah. Ẹ̀mí sì wí fún Filipi pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.” Filipi si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah, Filipi sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Filipi kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó. Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí: “A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa; àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan. Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún: Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀? Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.” Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?” Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìhìnrere ti Jesu fún un. Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitiisi?” Filipi sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitiisi rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọ́run ni.” Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Ìṣe àwọn Aposteli 8:26-38