Ìṣe àwọn Aposteli 3:1-16

Ìṣe àwọn Aposteli 3:1-16 YCB

Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán. Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ, Nígbà tí ó rí Peteru àti Johanu bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹmpili, ó ṣagbe. Peteru sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Johanu, ó ní “Wò wá!” Ó sì fiyèsí wọn, ó ń retí láti rí nǹkan láti gbà lọ́wọ́ wọn. Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ: Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.” Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun. Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run. Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run: Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe ní ẹnu-ọ̀nà Dáradára ti tẹmpili náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀. Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Peteru àti Johanu mú, gbogbo ènìyàn jùmọ̀ súre tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Solomoni, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ńlá. Nígbà tí Peteru sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, èéṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí èéṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn? Ọlọ́run Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jesu ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pilatu, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣẹ́ Ẹni Mímọ́ àti Olóòótọ́ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín. Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́. Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.