Ìṣe àwọn Aposteli 27:1-20

Ìṣe àwọn Aposteli 27:1-20 YCB

Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Itali, wọn fi Paulu àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Juliusi, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Augustu. Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa. Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí a sì kúrò níbẹ̀, a lọ lẹ́bàá Saipurọsi, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì. Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia. Níbẹ̀ ni balógun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-òkun Alekisandiria kan, ti ń lọ sí Itali; ó sì fi wa sínú rẹ̀. Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọ̀kánkán Knidu, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láààyè, a ba ẹ̀bá Krete lọ, lọ́kankán Salmoni; Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Lasea. Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn. Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.” Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ̀ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Paulu wí lọ. Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fonike, tí i ṣe èbúté Krete ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oòrùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oòrùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀. Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣe bí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń gba ẹ̀bá Krete lọ. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà. Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ. Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùṣù kan tí a ń pè Kauda, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjá ààbò. Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri. Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀; Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù. Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.