Ìṣe àwọn Aposteli 10:34-48

Ìṣe àwọn Aposteli 10:34-48 YCB

Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Judea, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Galili, lẹ́yìn bamitiisi ti Johanu wàásù rẹ̀. Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀. “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú. Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.” Bí Peteru sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti a ti kọ nílà tí wọ́n bá Peteru wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú. Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo. Nígbà náà ni Peteru dáhùn wí pé, “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin pe, kí a má bamitiisi àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?” Ó sì pàṣẹ kí a bamitiisi wọn ni orúkọ Jesu Kristi. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ọjọ́ mélòó kan.