Ìṣe àwọn Aposteli 1:15-26

Ìṣe àwọn Aposteli 1:15-26 YCB

Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà) ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu: Nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń ṣe tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí.” (Judasi fi èrè àìṣòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì ṣubú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde. Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.) Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé, “ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’ àti, “ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’ Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa. Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.” Wọn sì yan àwọn méjì, Josẹfu tí a ń pè ní Barsaba, (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Justu) àti Mattia. Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ aposteli yìí, èyí tí Judasi kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.” Wọ́n sì dìbò fún wọn; ìbò sí mú Mattia; a sì kà á mọ́ àwọn aposteli mọ́kànlá.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Ìṣe àwọn Aposteli 1:15-26