Ìṣe àwọn Aposteli 1:12-26

Ìṣe àwọn Aposteli 1:12-26 YCB

Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan. Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni: Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu; Filipi àti Tomasi; Bartolomeu àti Matiu; Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà. Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà) ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu: Nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń ṣe tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí.” (Judasi fi èrè àìṣòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì ṣubú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde. Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.) Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé, “ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’ àti, “ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’ Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa. Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.” Wọn sì yan àwọn méjì, Josẹfu tí a ń pè ní Barsaba, (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Justu) àti Mattia. Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ aposteli yìí, èyí tí Judasi kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.” Wọ́n sì dìbò fún wọn; ìbò sí mú Mattia; a sì kà á mọ́ àwọn aposteli mọ́kànlá.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Ìṣe àwọn Aposteli 1:12-26