2 Timotiu 3:1-9

2 Timotiu 3:1-9 YCB

Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.