Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè. “Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Eliṣa sì gbàdúrà, “OLúWA, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà OLúWA la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká.
Kà 2 Ọba 6
Feti si 2 Ọba 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Ọba 6:15-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò