Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia; Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnrawọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìhìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú. Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìhìnrere ẹlòmíràn.
Kà 2 Kọrinti 8
Feti si 2 Kọrinti 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Kọrinti 8:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò