Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú. Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú.
Kà 2 Kọrinti 5
Feti si 2 Kọrinti 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Kọrinti 5:8-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò