Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara; Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n báyìí, bí Ìhìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.
Kà 2 Kọrinti 4
Feti si 2 Kọrinti 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Kọrinti 4:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò