2 Kọrinti 12:1-10

2 Kọrinti 12:1-10 YCB

Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí. Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀. Pé a gbé e lọ sókè sí Paradise, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ. Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkára mi èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi. Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi, àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.