Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí, ó mọ odi kan lẹ́yìn ìlú Dafidi, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, àní ní àtiwọ ẹnu ibodè ẹja, ó sì yí orí òkè Ofeli ká; ó sì mọ ọ́n ga sókè gidigidi, ó sì fi balógun sínú gbogbo ìlú olódi Juda wọ̀n-ọn-nì. Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjèjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé OLúWA, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé OLúWA àti ní Jerusalẹmu; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú. Nígbà náà ni ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò. Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ-ọpẹ́ lórí rẹ̀. Ó sì sọ fún Juda láti sin OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Àwọn ènìyàn, ko tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga. Ṣùgbọ́n sí OLúWA Ọlọ́run wọn nìkan. Àwọn iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Manase pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìṣòótọ́, àti àwọn òpó níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìrántí àwọn aríran. Manase sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀. Amoni ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì. Ó ṣe búburú ní ojú OLúWA, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. Amoni rú ẹbọ sí gbogbo àwọn òrìṣà tí Manase baba rẹ̀ ti ṣe, ó sì sìn wọ́n. Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba rẹ̀ Manase. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLúWA: ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Amoni sì ń pọ̀ sì í. Àwọn oníṣẹ́ Amoni dìtẹ̀ sí i. Wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì mú Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Kà 2 Kronika 33
Feti si 2 Kronika 33
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Kronika 33:14-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò