Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye. Ni tirẹ pẹlu, emi o fi ẹjẹ majẹmu rẹ rán awọn igbèkun rẹ jade kuro ninu ihò ti kò li omi. Ẹ pada si odi agbara, ẹnyin onde ireti: ani loni yi emi sọ pe, emi o san a fun ọ ni igbàmejì.
Kà Sek 9
Feti si Sek 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sek 9:9-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò