Sek 7
7
OLUWA Kọ Ààwẹ̀ Àgàbàgebè
1O si ṣe li ọdun kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá ni ijọ kẹrin oṣù kẹsan, Kislefi;
2Nigbati nwọn rán Ṣereṣeri ati Regemmeleki, ati awọn enia wọn si ile Ọlọrun lati wá oju rere Oluwa.
3Ati lati bá awọn alufa ti o wà ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati awọn woli sọ̀rọ, wipe, Ki emi ha sọkun li oṣù karun, ki emi ya ara mi sọtọ, bi mo ti nṣe lati ọdun melo wonyi wá?
4Nigbana li ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun tọ̀ mi wá wipe,
5Sọ fun gbogbo awọn enia ilẹ na, ati fun awọn alufa, wipe, Nigbati ẹnyin gbawẹ̀ ti ẹ si ṣọ̀fọ li oṣù karun ati keje, ani fun ãdọrin ọdun wọnni, ẹnyin ha gbawẹ̀ si mi rara, ani si emi?
6Nigbati ẹ si jẹ, ati nigbati ẹ mu, fun ara nyin ki ẹnyin ha jẹ, ati fun ara nyin ki ẹnyin ha mu?
7Wọnyi kì ọ̀rọ ti Oluwa ti kigbe lati ọdọ awọn woli iṣãju wá, nigbati a ngbe Jerusalemu, ti o si wà li alafia, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ti o yi i ka kiri, nigbati a ngbe gusù ati pẹtẹlẹ?
Àìgbọràn ló fa Ìkólọ-sóko-Ẹrú
8Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Sekariah wá, wipe,
9Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀.
10Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀.
11Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́.
12Ani nwọn ṣe aiya wọn bi okuta adamanti, ki nwọn ki o má ba gbọ́ ofin, ati ọ̀rọ ti Ọluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ rán nipa ọwọ awọn woli iṣãju wá: ibinu nla si de lati ọdọ Ọluwa awọn ọmọ-ogun wá.
13O si ṣe, gẹgẹ bi o ti kigbe, ti nwọn kò si fẹ igbọ́, bẹ̃ni nwọn kigbe, ti emi kò si fẹ igbọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
14Mo si fi ãja tú wọn ka si gbogbo orilẹ-ède ti nwọn kò mọ̀. Ilẹ na si dahoro lẹhin wọn, ti ẹnikẹni kò là a kọja tabi ki o pada bọ̀: nwọn si sọ ilẹ ãyò na dahoro.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sek 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.