Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kọkanla, ti iṣe oṣù Sebati, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli wá, pe,
Mo ri li oru, si wò o, ọkunrin kan ngun ẹṣin pupa kan, on si duro lãrin awọn igi mirtili ti o wà ni ibi õji; lẹhìn rẹ̀ si li ẹṣin pupa, adíkalà, ati funfun gbe wà.
Nigbana ni mo wipe, Kini wọnyi oluwa mi? Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, emi o fi ohun ti wọnyi jẹ hàn ọ.
Ọkunrin ti o duro lãrin awọn igi mirtili si dahùn o si wipe, Wọnyi li awọn ti Oluwa ti rán lati ma rìn sokè sodò li aiye.
Nwọn si da angeli Oluwa ti o duro lãrin awọn igi mirtili na lohùn pe, Awa ti rìn sokè sodò já aiye, si kiyesi i, gbogbo aiye wà ni isimi, o si duro jẹ.
Nigbana ni angeli Oluwa na dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio fi ṣãnu fun Jerusalemu, ati fun awọn ilu-nla Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi?
Oluwa si fi ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ itùnu da angeli ti mba mi sọ̀rọ lohùn.
Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, Iwọ kigbe wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi nfi ijowu nla jowu fun Jerusalemu ati fun Sioni.
Emi si binu pupọ̀pupọ̀ si awọn orilẹ-ède ti o gbe jẹ: nitoripe emi ti binu diẹ, nwọn si ti kún buburu na lọwọ.
Nitorina bayi li Oluwa wi; mo padà tọ̀ Jerusalemu wá pẹlu ãnu; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, a o kọ ile mi sinu rẹ̀, a o si ta okùn kan jade sori Jerusalemu.
Ma ke sibẹ̀ pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; A o ma fi ire kún ilu-nla mi sibẹ̀; Oluwa yio si ma tù Sioni ninu sibẹ̀, yio si yàn Jerusalemu sibẹ̀.