O. Sol 7
7
1Ẹsẹ rẹ ti li ẹwà to ninu bata, iwọ ọmọ-alade! orike itan rẹ dabi ohun ọṣọ́, iṣẹ ọwọ ọlọgbọ́n oniṣọna.
2Iwọ́ rẹ dabi ago ti kò ṣe alaini ọti, ara rẹ dabi okiti alikama ti a fi lili yika.
3Ọmú rẹ mejeji dabi abo ọmọ agbọnrin meji ti iṣe ìbejì.
4Ọrùn rẹ dabi ile iṣọ ehin-erin; oju rẹ dabi adagun ni Heṣboni, lẹba ẹnu-bode Batrabbimu: imú rẹ dabi ile-iṣọ Lebanoni ti o kọju si ihà Damasku.
5Ori rẹ dabi Karmeli lara rẹ, ati irun ori rẹ bi purpili; a fi aidì irun rẹ di ọba mu.
6O ti li ẹwà to, o si ti dara to, iwọ olufẹ mi ninu adùn ifẹ!
7Iduro rẹ yi dabi igi ọ̀pẹ ati ọmú rẹ bi ṣiri eso àjara.
8Mo ni, emi o gùn ọ̀pẹ lọ, emi o di ẹka rẹ̀ mu: pẹlupẹlu nisisiyi ọmú rẹ pẹlu yio dabi ṣiri àjara, ati õrùn imú rẹ bi eso appili;
9Ati ẹnu rẹ bi ọti-waini ti o dara jù, ti o sọkalẹ kẹlẹkẹlẹ fun olufẹ mi, ti o nmu ki etè awọn ti o sùn ki o sọ̀rọ.
10Ti olufẹ mi li emi iṣe, ifẹ rẹ̀ si mbẹ si mi.
11Wá, olufẹ mi, jẹ ki a lọ si pápa; jẹ ki a wọ̀ si iletò wọnni.
12Jẹ ki a dide lọ sinu ọgba-àjara ni kutukutu; jẹ ki a wò bi àjara ruwe, bi itanná àjara ba là, ati bi igi granate ba rudi: nibẹ li emi o fi ifẹ mi fun ọ.
13Awọn eso mandraki fun ni li õrùn, li ẹnu-ọ̀na wa ni onirũru eso ti o wunni, ọtun ati ogbologbo, ti mo ti fi pamọ́ fun ọ, iwọ olufẹ mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Sol 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.