Iwọ o si wi fun mi pe, Kili ó ha tun ba ni wi si? Nitori tali o ndè ifẹ rẹ̀ lọ̀na? Bẹ̃kọ, iwọ enia, tani iwọ ti nda Ọlọrun lohùn? Ohun ti a mọ a ha mã wi fun ẹniti ti o mọ ọ pé, Ẽṣe ti iwọ fi mọ mi bayi? Amọ̀koko kò ha li agbara lori amọ̀, ninu ìṣu kanna lati ṣe apakan li ohun elo si ọlá, ati apakan li ohun elo si ailọlá? Njẹ bi Ọlọrun ba fẹ fi ibinu rẹ̀ hàn nkọ, ti o si fẹ sọ agbara rẹ̀ di mimọ̀, ti o si mu suru pupọ fun awọn ohun elo ibinu ti a ṣe fun iparun; Ati ki o le sọ ọrọ̀ ogo rẹ̀ di mimọ̀ lara awọn ohun elo ãnu ti o ti pèse ṣaju fun ogo, Ani awa, ti o ti pè, kì iṣe ninu awọn Ju nikan, ṣugbọn ninu awọn Keferi pẹlu? Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ. Yio si ṣe, ni ibi ti a gbé ti sọ fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o gbé pè wọn li ọmọ Ọlọrun alãye. Isaiah si kigbe nitori Israeli pe, Bi iye awọn ọmọ Israeli bá ri bi iyanrin okun, apakan li a ó gbala. Nitori Oluwa yio mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ lori ilẹ aiye, yio pari rẹ̀, yio si ke e kúru li ododo. Ati bi Isaiah ti wi tẹlẹ, Bikoṣe bi Oluwa awọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti sọ wa dabi Gomora.
Kà Rom 9
Feti si Rom 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 9:19-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò