Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́. Nitori ẹniti o kú, o bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ. Ṣugbọn bi awa ba bá Kristi kú, awa gbagbọ́ pe awa ó si wà lãye pẹlu rẹ̀: Nitori awa mọ̀ pé bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú, kò ni ikú mọ́; ikú kò ni ipa lori rẹ̀ mọ́. Nitori iku ti o kú, o kú si ẹ̀ṣẹ lẹ̃kan: nitori wiwà ti o wà lãye, o wà lãye si Ọlọrun. Bẹ̃ni ki ẹnyin pẹlu kà ara nyin bi okú si ẹ̀ṣẹ, ṣugbọn bi alãye si Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀; Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ fun ẹ̀ṣẹ bi ohun elo aiṣododo; ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹ̀ya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun. Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.
Kà Rom 6
Feti si Rom 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 6:6-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò