NJẸ kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara, ri? Nitori bi a ba da Abrahamu lare nipa iṣẹ, o ni ohun iṣogo; ṣugbọn kì iṣe niwaju Ọlọrun. Iwe-mimọ́ ha ti wi? Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u. Njẹ fun ẹniti o ṣiṣẹ a kò kà ère na si ore-ọfẹ bikoṣe si gbese. Ṣugbọn fun ẹniti kò ṣiṣẹ, ti o si ngbà ẹniti o nda enia buburu lare gbọ́, a kà igbagbọ́ rẹ̀ si ododo. Gẹgẹ bi Dafidi pẹlu ti pe oluwarẹ̀ na ni ẹni ibukun, ẹniti Ọlọrun kà ododo si laisi ti iṣẹ́, Wipe, Ibukún ni fun awọn ẹniti a dari irekọja wọn jì, ti a si bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si li ọrùn. Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́ fun Abrahamu si ododo. Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni. O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu: Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla.
Kà Rom 4
Feti si Rom 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 4:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò