Rom 3:1-20

Rom 3:1-20 YBCV

NJẸ anfani ki ha ni ti Ju? tabi kini ère ilà kíkọ? Pipọ lọna gbogbo; ekini, nitoripe awọn li a fi ọ̀rọ Ọlọrun le lọwọ. Njẹ ki ha ni bi awọn kan jẹ alaigbagbọ́? aigbagbọ́ wọn yio ha sọ otitọ Ọlọrun di asan bi? Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ. Ṣugbọn bi aiṣododo wa ba nyìn ododo Ọlọrun, kili awa o wi? Ọlọrun ti nfi ibinu rẹ̀ han ha ṣe alaiṣododo bi? (Mo fi ṣe akawe bi enia.) Ki a má ri: bi bẹ̃ni, Ọlọrun yio ha ṣe le dajọ araiye? Nitori bi otitọ Ọlọrun ba di pipọ si iyìn rẹ̀ nitori eke mi, ẽṣe ti a fi nda mi lẹjọ bi ẹlẹṣẹ mọ́ si? Ẽṣe ti a kò si wipe (gẹgẹ bi a ti nsọrọ wa ni ibi, ati gẹgẹ bi awọn kan ti nsọ pe, awa nwipe,) Ẹ jẹ ki a mã ṣe buburu, ki rere ki o le jade wá? awọn ẹniti ẹ̀bi wọn tọ́. Njẹ ki ha ni? awa ha san jù wọn bi? Kò ri bẹ̃ rara: nitori a ti fihan ṣaju pe ati awọn Ju ati awọn Hellene, gbogbo nwọn li o wà labẹ ẹ̀ṣẹ; Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan: Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun. Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan. Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn. Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun. Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.