NITORINA alairiwi ni iwọ ọkunrin na, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ ti ndajọ: nitori ninu ohun ti iwọ nṣe idajọ ẹlomiran, iwọ ndá ara rẹ lẹbi; nitori iwọ ti ndajọ nṣe ohun kanna.
Ṣugbọn awa mọ̀ pe idajọ Ọlọrun jẹ gẹgẹ bi otitọ si gbogbo awọn ti o nṣe irú ohun bawọnni.
Ati iwọ ọkunrin na ti nṣe idajọ awọn ti nṣe irú ohun bawọnni, ti iwọ si nṣe bẹ̃ na, iwọ ro eyi pe iwọ ó yọ ninu idajọ Ọlọrun?
Tabi iwọ ngàn ọrọ̀ ore ati ipamọra ati sũru rẹ̀, li aimọ̀ pe ore Ọlọrun li o nfà ọ lọ si ironupiwada?
Ṣugbọn gẹgẹ bi lile ati aironupiwada ọkàn rẹ, ni iwọ nfi ibinu ṣura fun ara rẹ de ọjọ ibinu ati ti ifihàn idajọ ododo Ọlọrun:
Ẹniti yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀:
Fun awọn ti nfi sũru ni rere-iṣe wá ogo ati ọlá ati aidibajẹ, ìye ainipẹkun;
Ṣugbọn fun awọn onijà, ti nwọn kò si gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ngbà aiṣododo gbọ́, irunu ati ibinu yio wà.
Ipọnju ati irora, lori olukuluku ọkàn enia ti nhuwa ibi, ti Ju ṣaju, ati ti Hellene pẹlu;
Ṣugbọn ogo, ati ọlá, ati alafia, fun olukuluku ẹni ti nhuwa rere, fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu:
Nitori ojuṣaju enia kò si lọdọ Ọlọrun.
Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ;
Nitori kì iṣe awọn olugbọ ofin li alare lọdọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn oluṣe ofin li a o dalare.
Nitori nigbati awọn Keferi, ti kò li ofin, ba ṣe ohun ti o wà ninu ofin nipa ẹda, awọn wọnyi ti kò li ofin, jẹ ofin fun ara wọn:
Awọn ẹniti o fihan pe, a kọwe iṣẹ ofin si wọn li ọkàn, ti ọkàn wọn si njẹ wọn lẹri, ti iro wọn larin ara wọn si nfi wọn sùn tabi ti o ngbè wọn,
Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi.
Ṣugbọn bi a ba npè iwọ ni Ju, ti o si simi le ofin, ti o si nṣogo ninu Ọlọrun,
Ti o si mọ̀ ifẹ rẹ̀, ti o si dán ohun ti o yàtọ wò, ẹniti a ti kọ li ofin;
Ti o si gbé oju le ara rẹ̀ pe iwọ li amọ̀na awọn afọju, imọlẹ awọn ti o wà li òkunkun,
Olukọ awọn alaimoye, olukọ awọn ọmọde, ẹniti o ni afarawe imọ ati otitọ ofin li ọwọ.
Njẹ iwọ ti o nkọ́ ẹlomiran, iwọ kò kọ́ ara rẹ? iwọ ti o nwasu ki enia ki o má jale, iwọ njale?
Iwọ ti o nwipe ki enia ki o máṣe panṣaga, iwọ nṣe panṣaga? iwọ ti o ṣe họ̃ si oriṣa, iwọ njà tẹmpili li ole?
Iwọ ti nṣogo ninu ofin, ni riru ofin iwọ bù Ọlọrun li ọlá kù?
Nitori orukọ Ọlọrun sá di isọrọ-buburu si ninu awọn Keferi nitori nyin, gẹgẹ bi a ti kọ ọ.
Nitori ikọla li ère lõtọ, bi iwọ ba pa ofin mọ́: ṣugbọn bi iwọ ba jẹ arufin, ikọla rẹ di aikọla.
Nitorina bi alaikọla ba pa ilana ofin mọ́, a kì yio ha kà aikọla rẹ̀ si ikọla bi?
Alaikọla nipa ti ẹda, bi o ba pa ofin mọ́, kì yio ha da ẹbi fun iwọ ti o jẹ arufin nipa ti iwe ati ikọla?
Kì iṣe eyi ti o farahan ni Ju, bẹni kì iṣe eyi ti o farahan li ara ni ikọla:
Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.