Ará, emi si bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣọ awọn ti nṣe ìyapa, ati awọn ti nmu ohun ikọsẹ̀ wá lodi si ẹkọ́ ti ẹnyin kọ́; ẹ si kuro ni isọ wọn. Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà. Nitori igbagbọ́ nyin tàn kalẹ de ìbi gbogbo. Nitorina mo ni ayọ̀ lori nyin: ṣugbọn emi fẹ ki ẹ jẹ ọlọgbọn si ohun ti o ṣe rere, ki ẹ si ṣe òpe si ohun ti iṣe buburu. Ọlọrun alafia yio si tẹ̀ Satani mọlẹ li atẹlẹsẹ nyin ni lọ̃lọ. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu nyin. Amin.
Kà Rom 16
Feti si Rom 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 16:17-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò