Rom 16:1-13

Rom 16:1-13 YBCV

MO fi Febe, arabinrin wa, le nyin lọwọ ẹniti iṣe diakoni ijọ ti o wà ni Kenkrea: Ki ẹnyin le gbà a ninu Oluwa, bi o ti yẹ fun awọn enia mimọ́, ki ẹnyin ki o si ràn a lọwọ iṣẹkiṣẹ ti o nwá ni iranlọwọ lọdọ nyin: nitori on pẹlu ti nṣe oluranlọwọ fun ẹni pipọ, ati fun emi na pẹlu. Ẹ kí Priskilla ati Akuila, awọn alabaṣiṣẹ mi ninu Kristi Jesu: Awọn ẹniti, nitori ẹmí mi, nwọn fi ọrùn wọn lelẹ: fun awọn ẹniti kì iṣe kiki emi nikan li o ndupẹ, ṣugbọn gbogbo ijọ larin awọn Keferi pẹlu. Ẹ si kí ijọ ti o wà ni ile wọn. Ẹ ki Epenetu, olufẹ mi ọwọn, ẹniti iṣe akọso Asia fun Kristi. Ẹ kí Maria, ti o ṣe lãla pipọ lori wa. Ẹ kí Androniku ati Junia, awọn ibatan mi, ati awọn ẹgbẹ mi ninu tubu, awọn ẹniti o ni iyìn lọdọ awọn Aposteli, awọn ẹniti o ti wà ninu Kristi ṣaju mi pẹlu. Ẹ kí Ampliatu olufẹ mi ninu Oluwa. Ẹ kí Urbani, alabaṣiṣẹ wa ninu Kristi, ati Staki olufẹ mi. Ẹ ki Apelle ẹniti a mọ̀ daju ninu Kristi. Ẹ kí awọn arãle Aristobulu. Ẹ kí Herodioni, ibatan mi. Ẹ kí awọn arãle Narkissu, ti o wà ninu Oluwa. Ẹ kí Trifena ati Trifosa, awọn ẹniti nṣe lãlã ninu Oluwa. Ẹ kí Persi olufẹ, ti o nṣe lãlã pipọ ninu Oluwa. Ẹ kí Rufu ti a yàn ninu Oluwa, ati iya rẹ̀ ati ti emi.