Rom 15:22-33

Rom 15:22-33 YBCV

Nitorina pẹlu li àye ṣe há fun mi li akoko wọnyi lati tọ̀ nyin wá. Ṣugbọn nisisiyi bi emi kò ti li àye mọ́ li ẹkùn wọnyi, bi emi si ti fẹ gidigidi lati ọdún melo wọnyi lati tọ̀ nyin wá, Nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ̀ nyin wá: nitori mo nireti pe emi o ri nyin li ọ̀na àjo mi, ati pe ẹ o mu mi já ọ̀na mi nibẹ̀ lati ọdọ nyin lọ, bi mo ba kọ kún fun ẹgbẹ nyin li apakan. Ṣugbọn nisisiyi mo nlọ si Jerusalemu lati ṣe iranṣẹ fun awọn enia mimọ́. Nitoriti o wù awọn ará Makedonia ati Akaia lati da owo jọ fun awọn talakà awọn enia mimọ́ ti o wà ni Jerusalemu. Nitõtọ ifẹ inu rere wọn ni; ajigbese wọn ni nwọn sá ṣe. Nitori bi o ba ṣepe a fi awọn Keferi ṣe alajọni ninu ohun ẹmí wọn, ajigbese si ni wọn lati fi nkan ti ara ta wọn lọrẹ. Nitorina nigbati mo ba ti ṣe eyi tan, ti mo ba si ti dí èdidi eso yi fun wọn tan, emi ó ti ọdọ nyin lọ si Spania. Mo si mọ pe, nigbati mo ba de ọdọ nyin, emi o wá ni kikún ibukún ihinrere Kristi. Mo si bẹ̀ nyin, ará, nitori Oluwa wa Jesu Kristi, ati nitori ifẹ Ẹmí, ki ẹnyin ki o ba mi lakaka ninu adura nyin si Ọlọrun fun mi; Ki a le gbà mi lọwọ awọn alaigbọran ni Judea ati ki iṣẹ-iranṣẹ ti mo ni si Jerusalemu le jẹ itẹwọgbà lọdọ awọn enia mimọ́. Ki emi ki o le fi ayọ̀ tọ̀ nyin wá nipa ifẹ Ọlọrun, ati ki emi le ni itura pọ pẹlu nyin. Njẹ ki Ọlọrun alafia ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.