Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju. Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ má ṣe ọlẹ; ẹ mã ni igbona ọkàn; ẹ mã sìn Oluwa; Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura; Ẹ mã pese fun aini awọn enia mimọ́; ẹ fi ara nyin fun alejò iṣe. Ẹ mã súre fun awọn ti nṣe inunibini si nyin: ẹ mã sure, ẹ má si ṣepè. Awọn ti nyọ̀, ẹ mã ba wọn yọ̀, awọn ti nsọkun, ẹ mã ba wọn sọkun. Ẹ mã wà ni inu kanna si ara nyin. Ẹ máṣe tọju ohun gíga, ṣugbọn ẹ mã tẹle awọn onirẹlẹ. Ẹ máṣe jẹ ọlọ́gbọn li oju ara nyin.
Kà Rom 12
Feti si Rom 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 12:10-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò