Ará, emi kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li òpe niti ohun ijinlẹ yi, ki ẹnyin má ba ṣe ọlọ́gbọn li oju ara nyin; pe ifọju bá Israeli li apakan, titi kíkún awọn Keferi yio fi de. Bẹ̃li a o si gbà gbogbo Israeli là; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ni Sioni li Olugbala yio ti jade wá, yio si yi aiwa-bi-Ọlọrun kuro lọdọ Jakọbu: Eyi si ni majẹmu mi fun wọn, nigbati emi o mu ẹ̀ṣẹ wọn kuro. Nipa ti ihinrere, ọtá ni nwọn nitori nyin: bi o si ṣe ti iyanfẹ ni, olufẹ ni nwọn nitori ti awọn baba. Nitori ailábámọ̀ li ẹ̀bun ati ipe Ọlọrun. Nitori gẹgẹ bi ẹnyin kò ti gbà Ọlọrun gbọ́ ri, ṣugbọn nisisiyi ti ẹnyin ri ãnu gbà nipa aigbagbọ́ wọn: Gẹgẹ bẹ̃li awọn wọnyi ti o ṣe aigbọran nisisiyi, ki awọn pẹlu ba le ri ãnu gbà nipa ãnu ti a fi hàn nyin. Nitori Ọlọrun sé gbogbo wọn mọ pọ̀ sinu aigbagbọ́, ki o le ṣãnu fun gbogbo wọn. Ã! ijinlẹ ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati ìmọ Ọlọrun! awamáridi idajọ rẹ̀ ti ri, ọ̀na rẹ̀ si jù awari lọ! Nitori tali o mọ̀ inu Oluwa? tabi tani iṣe ìgbimọ rẹ̀? Tabi tali o kọ́ fifun u, ti a o si san a pada fun u? Nitori lati ọdọ rẹ̀, ati nipa rẹ̀, ati fun u li ohun gbogbo: ẹniti ogo wà fun lailai. Amin.
Kà Rom 11
Feti si Rom 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 11:25-36
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò