Rom 10:5-21

Rom 10:5-21 YBCV

Mose sá kọ̀we rẹ̀ pe, ẹniti o ba ṣe ododo ti iṣe ti ofin, yio yè nipa rẹ̀. Ṣugbọn ododo ti iṣe ti igbagbọ́ sọ bayi pe, Máṣe wi li ọkàn rẹ pe, tani yio goke lọ si ọrun? (eyini ni, lati mu Kristi sọkalẹ:) Tabi, tani yio sọkalẹ lọ si ọgbun? (eyini ni, lati mu Kristi goke ti inu okú wá). Ṣugbọn kili o wi? Ọ̀rọ na wà leti ọdọ rẹ, li ẹnu rẹ, ati li ọkan rẹ: eyini ni, ọ̀rọ igbagbọ́, ti awa nwasu; Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là. Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala. Nitori iwe-mimọ́ wipe, Ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ oju ki yio ti i. Nitori kò si ìyatọ ninu Ju ati Hellene: nitori Oluwa kanna l'Oluwa gbogbo wọn, o si pọ̀ li ọrọ̀ fun gbogbo awọn ti nkepè e. Nitori ẹnikẹni ti o ba sá pè orukọ, Oluwa, li a o gbàlà. Njẹ nwọn o ha ti ṣe kepe ẹniti nwọn kò gbagbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbà ẹniti nwọn kò gburó rẹ̀ rí gbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbọ́ laisi oniwasu? Nwọn o ha si ti ṣe wasu, bikoṣepe a rán wọn? gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹsẹ awọn ti nwasu ihinrere alafia ti dara to, awọn ti nwãsu ihin ayọ̀ ohun rere! Ṣugbọn ki iṣe gbogbo wọn li o gbọ́ ti ihinrere. Nitori Isaiah wipe, Oluwa, tali o gbà ihin wa gbọ́? Njẹ nipa gbigbọ ni igbagbọ́ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọ̀rọ Ọlọrun. Ṣugbọn mo ni, Nwọn kò ha gbọ́ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ wọn si opin ilẹ aiye. Ṣugbọn mo ni, Israeli kò ha mọ̀ bi? Mose li o kọ́ wipe, Emi o fi awọn ti kì iṣe enia mu nyin jowú, ati awọn alaimoye enia li emi o fi bi nyin ninu. Ṣugbọn Isaiah tilẹ laiya, o si wipe, Awọn ti kò wá mi ri mi; awọn ti kò bère mi li a fi mi hàn fun. Ṣugbọn nipa ti Israeli li o wipe, Ni gbogbo ọjọ ni mo nà ọwọ́ mi si awọn alaigbọran ati alariwisi enia.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Rom 10:5-21