Ifi 8
8
Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Keje
1NIGBATI o si ṣí èdidi keje, kẹ́kẹ́ pa li ọrun niwọn àbọ wakati kan.
2Mo si ri awọn angẹli meje ti nwọn duro niwaju Ọlọrun; a si fi ipè meje fun wọn.
3Angẹli miran si wá, o si duro tì pẹpẹ, o ni awo turari wura kan; a si fi turari pupọ̀ fun u, ki o le fi i kún adura gbogbo awọn enia mimọ́ lori pẹpẹ wura ti mbẹ niwaju itẹ́.
4Ati ẹ̃fin turari na pẹlu adura awọn enia mimọ́ si gòke lọ siwaju Ọlọrun lati ọwọ́ angẹli na wá.
5Angeli na si mu awo turari na, o si fọ̀n iná ori pẹpẹ kun u, o si dà a sori ilẹ aiye: a si gbọ ohùn, ãra si san, mànamána si kọ, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀.
Àwọn Kàkàkí Mẹfa
6Awọn angẹli meje na ti nwọn ni ipè meje si mura lati fun wọn.
7Ekini si fun, yinyín ati iná ti o dàpọ̀ pẹlu ẹ̀jẹ si jade, a si dà wọn sori ilẹ aiye: idamẹta ilẹ aiye si jóna, idamẹta awọn igi si jóna, ati gbogbo koriko tutù si jóna.
8Angẹli keji si fun, a si wọ́ ohun kan bi òke nla ti njona sọ sinu okun: idamẹta okun si di ẹ̀jẹ;
9Ati idamẹta awọn ẹda ti mbẹ ninu okun ti o ni ẹmí si kú; ati idamẹta awọn ọkọ̀ si bajẹ.
10Angẹli kẹta si fun, irawọ̀ nla kan ti njo bi fitila si bọ́ lati ọrun wá, o si bọ sori idamẹta awọn odo ṣiṣàn, ati sori awọn orisun omi;
11A si npè orukọ irawọ na ni Iwọ idamẹta: awọn omi si di iwọ, ọ̀pọlọpọ enia si ti ipa awọn omi na kú, nitoriti a sọ wọn di kikorò.
12Angẹli kẹrin si fun, a si kọlu idamẹta õrùn, ati idamẹta oṣupa, ati idamẹta awọn irawọ, ki idamẹta wọn le ṣõkun, ki ọjọ maṣe mọlẹ fun idamẹta rẹ̀, ati oru bakanna.
13Mo si wò, mo si gbọ́ idì kan ti nfò li ãrin ọrun, o nwi li ohùn rara pe, Egbé, egbé, egbé, fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye nitori ohùn ipè iyoku ti awọn angẹli mẹta ti mbọwá fun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ifi 8: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.