Ọkan ninu awọn àgba na si wi fun mi pe, Máṣe sọkun: kiyesi i, Kiniun ẹ̀ya Juda, Gbòngbo Dafidi, ti bori lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀ mejẽje. Mo si ri li arin itẹ́ na, ati awọn ẹda alãye mẹrin na, ati li arin awọn àgba na, Ọdọ-Agutan kan duro bi eyiti a ti pa, o ni iwo meje ati oju meje, ti iṣe Ẹmí meje ti Ọlọrun, ti a rán jade lọ si ori ilẹ aiye gbogbo. O si wá, o si gbà a li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na. Nigbati o si gbà iwe na, awọn ẹda alãye mẹrin na, ati awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ niwaju Ọdọ-Agutan na, olukuluku nwọn ní dùru ati ago wura ti o kún fun turari ti iṣe adura awọn enia mimọ́. Nwọn si nkọ orin titun kan, wipe, Iwọ li o yẹ lati gbà iwe na, ati lati ṣí èdidi rẹ̀: nitoriti a ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹ̀jẹ rẹ ṣe ìrapada enia si Ọlọrun lati inu ẹyà gbogbo, ati ède gbogbo, ati inu enia gbogbo, ati orilẹ-ède gbogbo wá; Iwọ si ti ṣe wọn li ọba ati alufa si Ọlọrun wa: nwọn si njọba lori ilẹ aiye.
Kà Ifi 5
Feti si Ifi 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 5:5-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò