Ifi 3:1-13

Ifi 3:1-13 YBCV

ATI si angẹli ijọ ni Sardi kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o ni Ẹmí meje Ọlọrun, ati irawọ meje nì wipe; Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati pe iwọ ni orukọ pe iwọ mbẹ lãye, ṣugbọn iwọ kú. Mã ṣọra, ki o si fi ẹsẹ ohun ti o kù mulẹ, ti o ṣe tan lati kú: nitori emi kò ri iṣẹ rẹ ni pipé niwaju Ọlọrun. Nitorina ranti bi iwọ ti gbà, ati bi iwọ ti gbọ́, ki o si pa a mọ, ki o si ronupiwada. Njẹ, bi iwọ kò ba ṣọra, emi o de si ọ bi olè, iwọ kì yio si mọ̀ wakati ti emi o de si ọ. Iwọ ni orukọ diẹ ni Sardi, ti kò fi aṣọ wọn yi ẽri; nwọn o si mã ba mi rìn li aṣọ funfun: nitori nwọn yẹ. Ẹniti o ba ṣẹgun, on na li a o fi aṣọ funfun wọ̀; emi kì yio pa orukọ rẹ̀ rẹ́ kuro ninu iwe ìye, ṣugbọn emi o jẹwọ orukọ rẹ̀ niwaju Baba mi, ati niwaju awọn angẹli rẹ̀. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ati si angẹli ijọ ni Filadelfia kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o jẹ mimọ́ ni wi, ẹniti iṣe olõtọ, ẹniti o ni kọkọrọ Dafidi, ẹniti o ṣí, ti kò si ẹniti yio tì; ẹniti o si tì, ti kò si ẹniti yio ṣí. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ: kiyesi i, mo gbé ilẹkun ti o sí kalẹ niwaju rẹ, ti kò si ẹniti o le tì ì: pe iwọ li agbara diẹ, iwọ si pa ọ̀rọ mi mọ́, iwọ kò si sẹ́ orukọ mi. Kiyesi i, emi o mú awọn ti sinagogu Satani, awọn ti nwọn nwipe Ju li awọn, ti nwọn kì si iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn nṣeke; kiyesi i, emi o mu ki nwọn wá wolẹ niwaju ẹsẹ rẹ, ki nwọn si mọ pe emi ti fẹ ọ. Nitoriti iwọ ti pa ọ̀rọ sũru mi mọ́, emi pẹlu yio pa ọ mọ́ kuro ninu wakati idanwo ti mbọ̀wa de ba gbogbo aiye, lati dán awọn ti ngbe ori ilẹ aiye wo. Kiyesi i, emi mbọ̀ nisisiyi: di eyiti iwọ ni mu ṣinṣin, ki ẹnikẹni ki o máṣe gbà ade rẹ. Ẹniti o ba ṣẹgun, on li emi o fi ṣe ọwọ̀n ninu tẹmpili Ọlọrun mi, on kì yio si jade kuro nibẹ mọ́: emi o si kọ orukọ Ọlọrun mi si i lara, ati orukọ ilu Ọlọrun mi, ti iṣe Jerusalemu titun, ti o nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun mi wá, ati orukọ titun ti emi tikarami. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.