Ifi 2:20-23

Ifi 2:20-23 YBCV

Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa. Emi si fi sã fun u lati ronupiwada; kò si fẹ ronupiwada agbere rẹ̀. Kiyesi i, emi ó gbe e sọ si ori akete, ati awọn ti mba a ṣe panṣaga li emi o fi sinu ipọnju nla, bikoṣe bi nwọn ba ronupiwada iṣẹ wọn. Emi o si fi ikú pa awọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ijọ ni yio si mọ̀ pe, emi li ẹniti nwadi inu ati ọkàn: emi o si fifun olukuluku nyin gẹgẹ bi iṣẹ nyin.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Ifi 2:20-23