Ifi 2:18-29

Ifi 2:18-29 YBCV

Ati si angẹli ijọ ni Tiatira kọwe: Nkan wọnyi li Ọmọ Ọlọrun wi, ẹniti o ni oju rẹ̀ bi ọwọ́ iná, ti ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara; Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ifẹ rẹ, ati igbagbọ́, ati ìsin, ati sũru rẹ; ati pe iṣẹ rẹ ikẹhin jù ti iṣaju lọ. Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa. Emi si fi sã fun u lati ronupiwada; kò si fẹ ronupiwada agbere rẹ̀. Kiyesi i, emi ó gbe e sọ si ori akete, ati awọn ti mba a ṣe panṣaga li emi o fi sinu ipọnju nla, bikoṣe bi nwọn ba ronupiwada iṣẹ wọn. Emi o si fi ikú pa awọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ijọ ni yio si mọ̀ pe, emi li ẹniti nwadi inu ati ọkàn: emi o si fifun olukuluku nyin gẹgẹ bi iṣẹ nyin. Ṣugbọn ẹnyin ni mo nsọ fun, ẹnyin iyokù ti mbẹ ni Tiatira, gbogbo ẹnyin ti kò ni ẹkọ́ yi, ti kò mọ̀ ohun ijinlẹ Satani (bi nwọn ti nwi), emi kò dì ẹrù miran rù nyin. Ṣugbọn eyi ti ẹnyin ni, ẹ di i mu ṣinṣin titi emi o fi de. Ẹniti o ba si ṣẹgun, ati ẹniti o ba pa iṣẹ mi mọ́ titi de opin, emi o fun u li aṣẹ lori awọn orilẹ-ède: On o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn; bi ã ti ifọ́ ohun elo amọ̀koko li a o fọ́ wọn tũtu: bi emi pẹlu ti gba lati ọdọ Baba mi. Emi o si fi irawọ owurọ̀ fun u. Ẹniti o ba li eti, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmi nsọ fun awọn ijọ.