JOHANU si ìjọ meje ti mbẹ ni Asia: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, ti o si mbọ̀wá; ati lati ọdọ awọn Ẹmí meje ti mbẹ niwaju itẹ́ rẹ̀; Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, Ti o si ti fi wa jẹ́ ọba ati alufa fun Ọlọrun ati Baba rẹ̀; tirẹ̀ li ogo ati ijọba lai ati lailai. Amin.
Kà Ifi 1
Feti si Ifi 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 1:4-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò