Mo si yipada lati wò ohùn ti mba mi sọ̀rọ. Nigbati mo yipada, mo ri ọpá fitila wura meje; Ati lãrin awọn ọpá fitila na, ẹnikan ti o dabi Ọmọ enia, ti a wọ̀ li aṣọ ti o kanlẹ̀ de ẹsẹ, ti a si fi àmure wura dì li ẹgbẹ. Ori rẹ̀ ati irun rẹ̀ funfun bi ẹ̀gbọn owu, o funfun bi sno; oju rẹ̀ si dabi ọwọ́ iná; Ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara, bi ẹnipe a dà a ninu ileru; ohùn rẹ̀ si dabi iró omi pupọ̀. O si ni irawọ meje li ọwọ́ ọtún rẹ̀; ati lati ẹnu rẹ̀ wá ni idà oloju meji mimú ti jade: oju rẹ̀ si dabi õrùn ti o nfi agbara rẹ̀ ràn. Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.
Kà Ifi 1
Feti si Ifi 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 1:12-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò