O. Daf 94:1-23

O. Daf 94:1-23 YBCV

OLUWA, Ọlọrun ẹsan; Ọlọrun ẹsan, fi ara rẹ hàn. Gbé ara rẹ soke, iwọ onidajọ aiye: san ẹsan fun awọn agberaga. Oluwa, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu yio fi ma leri? Nwọn o ti ma dà ọ̀rọ nù ti nwọn o ma sọ ohun lile pẹ to? ti gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio fi ma fi ara wọn leri. Oluwa, nwọn fọ́ awọn enia rẹ tutu, nwọn si nyọ awọn enia-ini rẹ lẹnu. Nwọn pa awọn opó ati alejo, nwọn si pa awọn ọmọ alaini-baba. Sibẹ nwọn wipe, Oluwa kì yio ri i, bẹ̃li Ọlọrun Jakobu kì yio kà a si, Ki oye ki o ye nyin, ẹnyin ope ninu awọn enia: ati ẹnyin aṣiwere, nigbawo li ẹnyin o gbọ́n? Ẹniti o gbin eti, o le ṣe alaigbọ́ bi? ẹniti o da oju, o ha le ṣe alairiran? Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ́? on li ẹniti nkọ́ enia ni ìmọ. Oluwa mọ̀ ìro-inu enia pe: asan ni nwọn. Ibukún ni fun enia na ẹniti iwọ nà, Oluwa, ti iwọ si kọ́ lati inu ofin rẹ wá; Ki iwọ ki o le fun u ni isimi kuro li ọjọ ibi, titi a o fi wà iho silẹ fun enia buburu. Nitoripe Oluwa kì yio ṣa awọn enia rẹ̀ tì, bẹ̃ni kì yio kọ̀ awọn enia-ini rẹ̀ silẹ. Ṣugbọn idajọ yio pada si ododo: gbogbo ọlọkàn diduro ni yio si ma tọ̀ ọ lẹhin. Tani yio dide si awọn oluṣe buburu fun mi? tabi tani yio dide si awọn oniṣẹ ẹ̀ṣe fun mi? Bikoṣe bi Oluwa ti ṣe oluranlọwọ mi; ọkàn mi fẹrẹ joko ni idakẹ. Nigbati mo wipe, Ẹsẹ mi yọ́; Oluwa, ãnu rẹ dì mi mu. Ninu ọ̀pọlọpọ ibinujẹ mi ninu mi, itunu rẹ li o nmu inu mi dùn. Itẹ́ ẹ̀ṣẹ ha le ba ọ kẹgbẹ pọ̀, ti nfi ofin dimọ ìwa-ika? Nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si ọkàn olododo, nwọn si da ẹ̀jẹ alaiṣẹ lẹbi. Ṣugbọn Oluwa li àbo mi; Ọlọrun mi si li apata àbo mi, On o si mu ẹ̀ṣẹ wọn bọ̀ sori ara wọn, yio si ke wọn kuro ninu ìwa-buburu wọn: Oluwa Ọlọrun wa, yio ke wọn kuro.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa