O. Daf 90
90
IWE KẸRIN
(O. Daf 90—106)
Adura Mose, enia Ọlọrun
Ibi tí Agbára Ẹ̀dá Mọ
1OLUWA, iwọ li o ti nṣe ibujoko wa lati irandiran.
2Ki a to bí awọn òke nla, ati ki iwọ ki o to dá ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun.
3Iwọ sọ enia di ibajẹ; iwọ si wipe, Ẹ pada wá, ẹnyin ọmọ enia.
4Nitoripe igbati ẹgbẹrun ọdun ba kọja li oju rẹ, bi aná li o ri, ati bi igba iṣọ́ kan li oru.
5Iwọ kó wọn lọ bi ẹnipe ni ṣiṣan-omi; nwọn dabi orun; ni kutukutu nwọn dabi koriko ti o dagba soke.
6Ni Kutukutu o li àwọ lara, o si dàgba soke, li asalẹ a ké e lulẹ, o si rọ.
7Nitori awa di egbé nipa ibinu rẹ, ati nipa ibinu rẹ ara kò rọ̀ wa.
8Iwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ wa ka iwaju rẹ, ohun ìkọkọ wa mbẹ ninu imọlẹ iwaju rẹ.
9Nitori ọjọ wa gbogbo nyipo lọ ninu ibinu rẹ: awa nlo ọjọ wa bi alá ti a nrọ́.
10Adọrin ọdun ni iye ọjọ ọdun wa; bi o si ṣepe nipa ti agbara, bi nwọn ba to ọgọrin ọdun, agbara wọn lãla on ibinujẹ ni; nitori pe a kì o pẹ ke e kuro, awa a si fò lọ.
11Tali o mọ̀ agbara ibinu rẹ? gẹgẹ bi ẹ̀ru rẹ, bẹ̃ni ibinu rẹ.
12Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n.
13Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ.
14Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo.
15Mu inu wa dùn bi iye ọjọ ti iwọ pọ́n wa loju, ati iye ọdun ti awa ti nri buburu.
16Jẹ ki iṣẹ rẹ ki o hàn si awọn ọmọ-ọ̀dọ rẹ, ati ogo rẹ si awọn ọmọ wọn.
17Jẹ ki ẹwà Oluwa Ọlọrun wa ki o wà lara wa: ki iwọ ki o si fi idi iṣẹ ọwọ wa mulẹ lara wa, bẹ̃ni iṣẹ ọwọ wa ni ki iwọ ki o fi idi rẹ̀ mulẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 90: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.