O. Daf 81
81
Orin fún Àkókò Àsè
1KỌRIN soke si Ọlọrun, ipa wa: ẹ ho iho ayọ̀ si Ọlọrun Jakobu.
2Ẹ mu orin mimọ́, ki ẹ si mu ìlu wa, duru didùn pẹlu ohun-elo orin mimọ́.
3Ẹ fun ipè li oṣù titún, ni ìgbà ti a lana silẹ, li ọjọ ajọ wa ti o ni ironu.
4Nitori eyi li aṣẹ fun Israeli, ati ofin Ọlọrun Jakobu.
5Eyi li o dasilẹ ni ẹrí fun Josefu, nigbati o là ilẹ Egipti ja; nibiti mo gbe gbọ́ ede ti kò ye mi.
6Mo gbé ejika rẹ̀ kuro ninu ẹrù: mo si gbà agbọn li ọwọ rẹ̀.
7Iwọ pè ninu ipọnju, emi si gbà ọ; emi da ọ lohùn nibi ìkọkọ ãra: emi ridi rẹ nibi omi ija.
8Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si jẹri si ọ: Israeli, bi iwọ ba fetisi mi.
9Kì yio si ọlọrun miran ninu nyin; bẹ̃ni iwọ kì yio sìn ọlọrun àjeji.
10Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti jade wá: yà ẹ̀nu rẹ̀ gbòro, emi o si kún u.
11Ṣugbọn awọn enia mi kò fẹ igbọ́ ohùn mi; Israeli kò si fẹ ti emi.
12Bẹ̃ni mo fi wọn silẹ fun lile aiya wọn: nwọn si nrìn ninu ero ara wọn.
13Ibaṣepe awọn enia mi ti gbọ́ ti emi, ati ki Israeli ki o ma rìn nipa ọ̀na mi!
14Emi iba ti ṣẹ́ awọn ọta wọn lọgan, emi iba si ti yi ọwọ mi pada si awọn ọta wọn.
15Awọn akorira Oluwa iba ti fi ori wọn balẹ fun u; igba wọn iba si duro pẹ titi.
16Alikama daradara ni on iba ma fi bọ́ wọn pẹlu: ati oyin inu apata ni emi iba si ma fi tẹ́ ọ lọrun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 81: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.