Tún wa yipada, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là. Iwọ ti mu ajara kan jade ti Egipti wá: iwọ ti tì awọn keferi jade, iwọ si gbin i. Iwọ ṣe àye silẹ fun u, iwọ si mu u ta gbòngbo jinlẹ̀, o si kún ilẹ na. A fi ojiji rẹ̀ bò awọn òke mọlẹ, ati ẹka rẹ̀ dabi igi kedari Ọlọrun. O yọ ẹka rẹ̀ sinu okun, ati ọwọ rẹ̀ si odò nla nì. Ẽṣe ti iwọ ha fi ya ọgbà rẹ̀ bẹ̃, ti gbogbo awọn ẹniti nkọja lọ li ọ̀na nká a? Imado lati inu igbo wá mba a jẹ, ati ẹranko igbẹ njẹ ẹ run. Yipada, awa mbẹ ọ, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: wolẹ lati ọrun wá, ki o si wò o, ki o si bẹ àjara yi wò: Ati agbala-àjara ti ọwọ ọtún rẹ ti gbin, ati ọmọ ti iwọ ti mule fun ara rẹ. O jona, a ke e lulẹ: nwọn ṣegbe nipa ibawi oju rẹ. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà lara ọkunrin ọwọ ọtún rẹ nì, lara ọmọ-enia ti iwọ ti mule fun ara rẹ. Bẹ̃li awa kì yio pada sẹhin kuro lọdọ rẹ: mu wa yè, awa o si ma pè orukọ rẹ. Tún wa yipada, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.
Kà O. Daf 80
Feti si O. Daf 80
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 80:7-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò