O. Daf 61

61
Adura Ààbò
1GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi.
2Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ.
3Nitori iwọ li o ti nṣe àbo fun mi, ati ile-iṣọ agbara lọwọ ọta nì.
4Emi o joko ninu agọ rẹ lailai: jẹ ki emi ri àbo ni iyẹ-apa rẹ.
5Nitoripe iwọ, Ọlọrun, li o ti gbọ́ ẹjẹ́ mi: iwọ ti fi ogún awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ fun mi.
6Iwọ o fa ẹmi ọba gùn: ati ọjọ ọdun rẹ̀ bi atiran-diran.
7On o ma gbe iwaju Ọlọrun lailai; pèse ãnu ati otitọ, ti yio ma ṣe itọju rẹ̀.
8Bẹ̃li emi o ma kọrin iyìn si orukọ rẹ lailai, ki emi ki o le ma san ẹjẹ́ mi li ojojumọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 61: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀